Curso disponível
Koronafairọsi jẹ́ ẹbí ńlá ti kòkòrò kan èyítí a mọ̀ pé ń ṣokùnfà àìsan láti otútù tó wọ́pọ̀ sí àwọn àrùn tó lágbára bíi Àrùn Mímí Middle East (MERS) àti Àrùn Mímí Tó Lágbára (SARS).
Gbajúgbajà koronafairọsi (COVID-19) kan ní a rí ní ọdún 2019 ní Wuhan, China. Èyí jẹ́ koronafairọsi titun kan èyítí a kò rí tẹ́lẹ̀ láàrín ọmọnìyàn.
Ẹ̀kọ́ yìí ń pèsè àfihàn gbogbogbò sí COVID-19 àti àwọn kòkòrò mímí tí ń jẹyọ a sì ṣeé fún àwọn akọ́ṣẹ́mọṣẹ́ ìlera gbogbo ènìyàn, àwọn adarí ìṣẹ̀lẹ̀ àti àwọn òṣìṣẹ́ tí ń ṣiṣẹ́ fún United Nations, àwọn àjọ àgbáyé àti àwọn NGO.
A fún àrùn yìí ní orúkọ gbogbogbò lẹ́yìn tí a ṣẹ̀dá ohun èlò, bí a dá dárúkọ nCoV èyí túmọ̀ sí COVID-19, àrùn àkóràn èyití koronafairọsi tí a ṣẹ̀ṣẹ̀ ṣàwárí ṣokùnfà.
Jọwọ ṣe akiyesi pe akoonu ti iṣẹ-ẹkọ yii ti wa ni atunyẹwo lọwọlọwọ lati ṣe afihan itọsọna to ṣẹṣẹ julọ. O le wa alaye imudojuiwọn lori awọn koko-ọrọ ti o jọmọ COVID-19 ninu awọn iṣẹ ikẹkọ atẹle:
Ajẹsara: ikanni awọn ajesara COVID-19
Awọn iwọn IPC: IPC fun COVID-19
Idanwo aisan ti o ni kiakia Antigen: 1) SARS-CoV-2 antijeni ti o ni kiakia idanwo aisan; 2) Awọn imọran pataki fun imuse SARS-CoV-2 antigen RDT
Jọwọ ṣakiyesi: Awọn ohun elo wọnyi ni imudojuiwọn kẹhin ni 16/12/2020.
Ẹ̀kọ́ yìí náà tún wà nílẹ̀ fún àwọn èdè wọ̀nyí:
English - français - Español - 中文 - Português - العربية - русский - Türkçe - српски језик - فارسی - हिन्दी, हिंदी - македонски јазик - Tiếng Việt - Indian sign language - magyar - Bahasa Indonesia - বাংলা - اردو - Kiswahili - አማርኛ - ଓଡିଆ - Hausa - Tetun - Deutsch - Asụsụ Igbo - ਪੰਜਾਬੀ - isiZulu - Soomaaliga - Afraan Oromoo - دری - Kurdî - پښتو - मराठी - Fulfulde- සිංහල - Latviešu valoda - తెలుగు - Esperanto - ภาษาไทย - chiShona - Kreyòl ayisyen - Казақ тілі - தமிழ் - Ελληνικά
Ọ̀rọ̀ àkótán: Ẹ̀kọ́ yìí ń pèsè àfihàn gbogbogbò sí àwọn kòkòrò mímí tí ń jẹyọ, èyí tó pẹ̀lú gbajúgbajà koronafairọsi. Ní òpin ẹ̀kọ́ yìí, o gbọ́dọ̀ le ṣàlàyé:
Àwọn orísun wà tó sopọ̀ ẹ̀kọ́ kọ̀ọ̀kan láti le ràn ọ́ lọ́wọ́ láti kẹ́kọ̀ọ́ síwájú síi lórí àkórí náà.
Èròngbà ìkẹ́kọ̀ọ́: Ṣàlàyé àwọn ìlànà pàtàkì ti àwọn kòkòrò mímí tí ń jẹyọ àti bí o ti le dáhùn dáradára sí àjàkálẹ̀ àrùn kan.
Àkókò ẹ̀kọ́: Bíi wákàtí 3.
Àwọn ìwé ẹ̀rí: Àkọsílẹ̀ Àṣeyọrí má a wà nílẹ̀ fún gbogbo olùkópa tó bá gbà ó kéré tán ìdá ọgọ́rin ninu ọgọ́rùn àpapọ̀ àmì tó wà fún gbogbo àwọn ìbéèrè. Awọn olukopa ti o gba Igbasilẹ Aṣeyọri tun le ṣe igbasilẹ Badge Ṣiṣi fun iṣẹ ikẹkọ yii. Tẹ nibi lati ko bi.
Tí a túmọ̀ sí èdè Yorùbá nípasẹ̀ ẹnìkan tó yọ̀nda láti Emerging respiratory viruses, including COVID-19: methods for detection, prevention, response and control, 2020. WHO kò ní dáhùn fún àkóónú tàbí ìṣedéédé ti ìtúmọ̀ èdè yìí. Tó bá wáyé wípé àìdọ́gba wà láàrín ìtúmọ̀ èdè Gẹ̀ẹ́sì àti èdè Yorùbá náà, ojúlówó ẹ̀yà ti èdè Gẹ̀ẹ́sì ní yóò jẹ́ olúborí àti ẹ̀yà tó dájú jùlọ.
WHO kò ṣàyẹ̀wò ìtúmọ̀ èdè yìí. A ṣe ohun èlò yìí fún èrèdí àtìlẹ́yìn ẹ̀kọ́ nìkan.