Course is available
Àwọn abala ètò ẹ̀kọ́ orí ayélujára tó rọrùn lati lò yìí, yóò kọ́ ọ ní onírúurú ọgbọ́n ti o lè lò nílé pẹ̀lú ọmọ rẹ. Àfojúsùn ẹ̀kọ́ yìí ni láti jẹ́ agbátẹrù àwọn ọ̀nà láti lo eré ojoojúmọ́ àti àwọn isé ilé bí àfààní fún ẹ̀kọ́ àti ìdàgbàsókè papajùlọ àwọn ọ̀nà tí o lè fi gbátẹrù ọmoọ rẹ láti jẹ́ kí ìsòro rẹ̀ kó tún bọ pegedé, ọ̀nà tí o le fi báa sọ̀rọ̀ àti ọ̀nà tí o le gbà láti jẹ́ kí ó le máa wùwà tó dára àti láti kọ́ọ ní ọ̀nà titun fún ìgbé ayé ojoojúmọ́.
Ẹni tó ya fọ́tò yìí: WHO / Blink Media - D. Valencia
Jọwọ ṣakiyesi: Awọn ohun elo wọnyi ni imudojuiwọn kẹhin nii 31/03/2022.
Ẹkọ yii tun wa ni:
English - मराठी - हिन्दी, हिंदी
Ẹ̀kọ́ yìí wà fún àwọn olùtójú àwọn ọmọ tí ọjọ́ orí wọn jẹ́ ọmọ ọdún méjì sí mẹ́ẹ̀sán, tí wọ́n ní idádúró ní idàgbàsókè tàbí ti wọn je àkàndá, pàápá jùlọ ní abala ìbánisọ̀rọ̀ àti ìbániseré (ìbánidọ̀rẹ́) wọn. Kò nílò pé a se àyèwò okùnfà àìsàn náà. Ìfojúsùn ẹ̀kọ́ yìí ni láti mú agbára olùtójú dára síi láti lo eré síse ojoojúmọ́ àti isẹ́ ilé bí anfààní láti ran ibánisọ̀rọ̀ àwọn ọmọ wọn lọ́wọ́, bí wọ́n ti ń ṣiṣẹ́, ìwà tí ó dára àti ìgbé ayé ojoojúmọ́, nípa síse bẹ̀ẹ̀ à hún ran ìgbé ayé àwọn olùtọ́jú lọ́wọ́. Ẹ̀kọ́ yìí dálé lórí Ètò è̩kó̩ ayelujara WHO fún Àmòjútó àwo̩n Ìdílé pè̩lú àwo̩n O̩mo̩ tóní Ìdádúró ní Ìdàgbàsókè tàbí àwo̩n Àkàndá O̩mo̩.
Bí a ṣe lè lo ètò ẹ̀kọ́ yìí
Ó dára láti bẹ̀ẹrẹ̀ pẹ̀lú ọ̀rọ̀ ìsájú láti le mọ̀ dáadáa nípa ẹ̀kọ́ yìí, kí á sì parí àwọn abala náà ní sísẹ̀ntẹ̀lé. Ìdí ni wípé àwọn ogbọ́n tí à ń kọ́ náà ń ṣiṣẹ́ papọ̀ pẹ̀lú ara wọn ni. Fún abala kọ̀ọ̀kan, a óò ní kí o ṣe àmúlò àwọn ọgbọ́n kan nínú ilé pẹ̀lú ọmọ re. A gbà ọ́ n’ímọ̀ràn pé kí o ṣe abala kan ní ọjọ́ mẹ́rin mẹ́rin sí máàrún kí o ba lè ní ànfààní lati ṣe àmúlò àwọn ǹkan tí o ti kọ́. Èyí túnmọ̀ sí wípé yóò gbà ọ́ tó oṣù méjì àt’ààbọ̀ lati lè parí ètò ẹ̀kọ́ yìí. A gbà ọ́ ní ìyànjú pé kí o lo ìwé àkọsílẹ̀ bí ètò ẹ̀kọ́ yìí bá ṣe ń lọ, kí o sì ri dájú wípé ò ń ṣe àkọsílẹ̀ gbogbo ohun tí o ń kọ́ nínú ṣíṣe àmúlò ètò ẹ̀kọ́ náà nínú ilé. Àwọn abala yìí yóò tọ́ọ sọ́nà lati ṣe èyí. Ìwé àkọsílẹ̀ kan wà fún ètò eko yìí èyí tí o lè tẹ̀ jade tàbí lò lórí ẹ̀rọ ayélujára— ó wà ní abala “dọ́kúmẹntì” ètò ẹ̀kọ́ yìí. Awon àfikún ìtọ́ni wà nínú ọ̀rọ̀ ìsàájú sí ètò ẹ̀kọ́ àti nínú ìwé àkọsílẹ̀.
Iye akoko ti eto yii yoo gba ọ Bíi wákàtí mẹjo
Àwọn Ìwé ẹ̀rí
Gbogbo àwọn olùkópa tí wọ́n gba ìdá ọgọ́rùn-ún ọgọ́rùn-ún ọgọ́rùn-ún ọgọ Awọn olukopa pẹlu Ẹbun fun Iwe-ẹri Moye Ẹkọ le gba ohun elo ti a npe ni "Open Badge," eyiti o wa fun gbigba lati ayelujara ati fifi sori ẹrọ lori awọn ẹrọ alagbeka wọn. Tẹ ibi láti mọ bí o ṣe máa ṣe èyí. .
A Se áyan ògbufọ̀ rẹ̀ sí ède Yorùbá láti inú ètò ẹ̀kọ́orí ayélujára ti WHO fún àwọn ìdílé pẹlú àwọn ọmọ tóní ìdádúró ní ìdàgbàsókè tàbí àwọn àkàndá omo tí ọdún 2021. Ohun tí ó wà nínú áyan ògbufọ̀ yìí àti bí ó i múná dóko tó, kòsí lọ́wọ́ àjọ WHO. Bí awuyewuye bá súyọ lá'árin ohun tí a kọ lédè gẹ̀ẹ́sì àti áyan ògbufọ̀ rẹ̀ sì èdè yorùbá, ohun tí a kọ lédè gẹ̀ẹ́sì ni yóò lékè. Àjọ WHO kò bẹ iṣẹ́ yìí wò. Ohun èlò yí wà fún ẹ̀kọ́ nìkan.