Course is available

Ètò è̩kó̩ orí ayélujára ti WHO fún Àmójútó àwo̩n Ìdílé pè̩lú àwo̩n O̩mo̩ tó ní Ìdádúró nípa Ìdàgbàsókè tàbí àwo̩n Àkàndá O̩mo̩

Offered by OpenWHO
Ètò è̩kó̩ orí ayélujára ti WHO fún Àmójútó àwo̩n Ìdílé pè̩lú àwo̩n O̩mo̩ tó ní Ìdádúró nípa Ìdàgbàsókè tàbí àwo̩n Àkàndá O̩mo̩

Àwọn abala ètò ẹ̀kọ́ orí ayélujára tó rọrùn lati lò yìí, yóò kọ́ ọ ní onírúurú ọgbọ́n ti o lè lò nílé pẹ̀lú ọmọ rẹ. Àfojúsùn ẹ̀kọ́ yìí ni láti jẹ́ agbátẹrù àwọn ọ̀nà láti lo eré ojoojúmọ́ àti àwọn isé ilé bí àfààní fún ẹ̀kọ́ àti ìdàgbàsókè papajùlọ àwọn ọ̀nà tí o lè fi gbátẹrù ọmoọ rẹ láti jẹ́ kí ìsòro rẹ̀ kó tún bọ pegedé, ọ̀nà tí o le fi báa sọ̀rọ̀ àti ọ̀nà tí o le gbà láti jẹ́ kí ó le máa wùwà tó dára àti láti kọ́ọ ní ọ̀nà titun fún ìgbé ayé ojoojúmọ́.

Ẹni tó ya fọ́tò yìí: WHO / Blink Media - D. Valencia

Jọwọ ṣakiyesi: Awọn ohun elo wọnyi ni imudojuiwọn kẹhin nii 31/03/2022.

Self-paced
Language: Yorùbá

Course information

Ẹkọ yii tun wa ni:

English - मराठी - हिन्दी, हिंदी

Ẹ̀kọ́ yìí wà fún àwọn olùtójú àwọn ọmọ tí ọjọ́ orí wọn jẹ́ ọmọ ọdún méjì sí mẹ́ẹ̀sán, tí wọ́n ní idádúró ní idàgbàsókè tàbí ti wọn je àkàndá, pàápá jùlọ ní abala ìbánisọ̀rọ̀ àti ìbániseré (ìbánidọ̀rẹ́) wọn. Kò nílò pé a se àyèwò okùnfà àìsàn náà. Ìfojúsùn ẹ̀kọ́ yìí ni láti mú agbára olùtójú dára síi láti lo eré síse ojoojúmọ́ àti isẹ́ ilé bí anfààní láti ran ibánisọ̀rọ̀ àwọn ọmọ wọn lọ́wọ́, bí wọ́n ti ń ṣiṣẹ́, ìwà tí ó dára àti ìgbé ayé ojoojúmọ́, nípa síse bẹ̀ẹ̀ à hún ran ìgbé ayé àwọn olùtọ́jú lọ́wọ́. Ẹ̀kọ́ yìí dálé lórí Ètò è̩kó̩ ayelujara WHO fún Àmòjútó àwo̩n Ìdílé pè̩lú àwo̩n O̩mo̩ tóní Ìdádúró ní Ìdàgbàsókè tàbí àwo̩n Àkàndá O̩mo̩.

Bí a ṣe lè lo ètò ẹ̀kọ́ yìí

Ó dára láti bẹ̀ẹrẹ̀ pẹ̀lú ọ̀rọ̀ ìsájú láti le mọ̀ dáadáa nípa ẹ̀kọ́ yìí, kí á sì parí àwọn abala náà ní sísẹ̀ntẹ̀lé. Ìdí ni wípé àwọn ogbọ́n tí à ń kọ́ náà ń ṣiṣẹ́ papọ̀ pẹ̀lú ara wọn ni. Fún abala kọ̀ọ̀kan, a óò ní kí o ṣe àmúlò àwọn ọgbọ́n kan nínú ilé pẹ̀lú ọmọ re. A gbà ọ́ n’ímọ̀ràn pé kí o ṣe abala kan ní ọjọ́ mẹ́rin mẹ́rin sí máàrún kí o ba lè ní ànfààní lati ṣe àmúlò àwọn ǹkan tí o ti kọ́. Èyí túnmọ̀ sí wípé yóò gbà ọ́ tó oṣù méjì àt’ààbọ̀ lati lè parí ètò ẹ̀kọ́ yìí. A gbà ọ́ ní ìyànjú pé kí o lo ìwé àkọsílẹ̀ bí ètò ẹ̀kọ́ yìí bá ṣe ń lọ, kí o sì ri dájú wípé ò ń ṣe àkọsílẹ̀ gbogbo ohun tí o ń kọ́ nínú ṣíṣe àmúlò ètò ẹ̀kọ́ náà nínú ilé. Àwọn abala yìí yóò tọ́ọ sọ́nà lati ṣe èyí. Ìwé àkọsílẹ̀ kan wà fún ètò eko yìí èyí tí o lè tẹ̀ jade tàbí lò lórí ẹ̀rọ ayélujára— ó wà ní abala “dọ́kúmẹntì” ètò ẹ̀kọ́ yìí. Awon àfikún ìtọ́ni wà nínú ọ̀rọ̀ ìsàájú sí ètò ẹ̀kọ́ àti nínú ìwé àkọsílẹ̀.

Iye akoko ti eto yii yoo gba ọ Bíi wákàtí mẹjo

Àwọn Ìwé ẹ̀rí

Gbogbo àwọn olùkópa tí wọ́n gba ìdá ọgọ́rùn-ún ọgọ́rùn-ún ọgọ́rùn-ún ọgọ Awọn olukopa pẹlu Ẹbun fun Iwe-ẹri Moye Ẹkọ le gba ohun elo ti a npe ni "Open Badge," eyiti o wa fun gbigba lati ayelujara ati fifi sori ẹrọ lori awọn ẹrọ alagbeka wọn. Tẹ ibi láti mọ bí o ṣe máa ṣe èyí. .

A Se áyan ògbufọ̀ rẹ̀ sí ède Yorùbá láti inú ètò ẹ̀kọ́orí ayélujára ti WHO fún àwọn ìdílé pẹlú àwọn ọmọ tóní ìdádúró ní ìdàgbàsókè tàbí àwọn àkàndá omo tí ọdún 2021. Ohun tí ó wà nínú áyan ògbufọ̀ yìí àti bí ó i múná dóko tó, kòsí lọ́wọ́ àjọ WHO. Bí awuyewuye bá súyọ lá'árin ohun tí a kọ lédè gẹ̀ẹ́sì àti áyan ògbufọ̀ rẹ̀ sì èdè yorùbá, ohun tí a kọ lédè gẹ̀ẹ́sì ni yóò lékè. Àjọ WHO kò bẹ iṣẹ́ yìí wò. Ohun èlò yí wà fún ẹ̀kọ́ nìkan.

What you'll learn

  • Sàlàyé àwọn ọ̀nà tí ó le gbà ni ìfirakínra pẹ̀lú ọmọ re nípa gbígbádùn àti pínpín isẹ́ ojoojúmọ́.
  • Sàlàyé àwọn ọ̀nà tí o le gbà ran ọmọ rẹ lọ́wọ́ láti le bánisọ̀rọ̀ àti láti lè kọ́ ohun titun.
  • Sàlàyé àwọn ọ̀nà tí o le fi ran omo rẹ lọ́wọ́ láti túbọ̀ maa fi àwọn ìwà tí ó dara hàn àti kí ìwa oníjàngbọ̀n lè dínkù.
  • Sàlàyé àwọn ọ̀nà tí o le fi ran ọmọ rẹ lọ́wọ́ láti kọ́ àwọn ọgbọ́n tí ó lè fi gbé ìgbé ayé ojoojúmọ́ pẹ̀lú ìrànlọ́wọ́ rẹ.
  • Sàpèjúwe àwọn ọ̀nà láti ran ìlera àti ìgbayégbádùn rẹ lọ́wọ́.

Course contents

  • Ọ̀rọ̀ ìsáájú:

    Ètò ẹ̀kọ́ ní sókí
  • Abala Kìíní: Síso̩ Àwo̩n O̩mo̩dé di Olùkópa:

    Nínú abala yìí ìwo̩ yíò mò̩ bí o tile: Mo̩ okun àti àléébù o̩mo̩ re̩; Sàwárí àwo̩n ohun tí o̩mo̩ re̩ fé̩ràn; Sà’kíyèsí àwo̩n ìwùwàsí o̩mo̩ re̩ nínú iṣẹ́ síse.
  • Abala kejì: Títẹ̀síwájú lati ri wípé àwọn ọmọ ń kópa:

    Ní abala yìí, ìwọ yóò kọ́ bí o ó ṣe: Ṣe àgbékalẹ̀ àyíká tí yóò ṣe ìrànwọ́ fún kíkópa pẹ̀lú ọmọ ọ̀ rẹ. Bọ́ sí iwájú ọmọọ̀ rẹ kío sì fún ọmọ rẹ ní ànfààní lati yan oríṣiríṣi ǹkan tí ó fẹ́ lati lè mú ìtẹ̀síwájú bá ìkópa.
  • Abala Kẹta: Bí a ṣe lè jẹ́ kí àwọn ọmọ kópá:

    Nínú abala yìí wàá kọ: Síwájú si nípa àwọn ìdádúró àti jíjẹ́ àkàndá ẹ̀dá nípa ìdàgbàsókè; Nípa àwọn ìgbàgbọ́ tó wọ́pọ̀ tí àwọn ènìyàn ní nípa ǹkan yìí ṣùgbọn tí wọn kò jẹ́ òótọ́; Ìdí tí pínpín ìkópa ṣe ṣe pàtàkì fún ẹ̀kọ́ ọmọ rẹ.
  • Abala Ke̩rin: Mímú Àwo̩n O̩mo̩dé Kópa nínú Ìbárae̩nis̩epò̩:

    Nínú abala yìí oó kò̩ó̩ láti: Ké̩kò̩ó̩ lórí àwo̩n ìs̩e ìdárayá àti is̩é̩ rere pè̩lú o̩mo̩ re̩; Sàkíyèsí nígbà tí o̩mo̩ re̩ bá ní ìwúrí àti nígbà tí ó bá fé̩ràn ìs̩e kan; Sàkíyèsí ìwà rere àti pé kí o yin o̩mo̩ re̩ nígbà tíó bá n s̩is̩é̩.
  • Abala karùn-ún: Ṣíṣe ìrànlọ́wọ́ fún ọmọ láti pín ìkópa nínú eré àti àwọn ìṣe ojoojúmọ́ ní ilé:

    Nínú abala yìí, o ó kọ́ bí o ṣe lè: Ṣe àgbékalẹ̀ eré àti ìṣe ìgbàdégbà nínu ilé èyí tí o lè ṣe pẹ̀lù ọmọọ̀ rẹ ní ojoojúmọ́; Ní ìfarakínra pẹ̀lú ọmọọ̀ rẹ àti bí ẹ ṣe lè jùmọ pín ìkópa ninu àwọn ìṣe ìgbàdégbà; Jẹ́ kí ọmọọ̀ rẹ tẹ̀síwájú láti máa nìfẹ́ sí ìṣe àjùmọ̀ṣe.
  • Abala Kefà: Ríran Àwọn Ọmọdé Lọ́wọ́ Lati Kópa Nínú Àwọn Ìṣe Ìgbàdégbà Nínú Eré Ṣíṣe:

    Nínú abala yìí, ìwọ yóò kọ́ nípa bí o ṣe lè: Ṣe àgbékalẹ̀ àwọn eré tí o lè ṣe pẹ̀lú ọmọọ̀ rẹ; Mú kí ọmọọ̀ rẹ ó nifẹ sí ohun tí ó ńṣe àti lati ran ọmọọ̀ rẹ lọ́wọ́ lati pín ìkópa fún àkókò tí ó pẹ́ síi; Àti wá ojutu sí àwọn ìṣòro tí o bá kojú nígbà tí o bá ń bá ọmọọ̀ rẹ ṣeré.
  • Abala Keje: Níní Òye Ìbárae̩nisò̩rò̩:

    Nínú abala yìí ìwo̩ yíò kó̩ nípa: Ò̩nà tí àwo̩n o̩mo̩dé ngbà bánisò̩rò̩ láì lo ò̩rò̩; bí o ti lè sàwárí, té̩tísílẹ̀ àti fèsì sí àwo̩n ìbánisò̩rò̩ o̩mo̩dé nínú is̩é̩ ojoojúmó̩.
  • Abala Kẹ́jọ: Mímú ìdàgbàsókè bá ọ̀nà ìbáraẹnisọ̀rọ̀:

    Ní abala yìí, wàá kọ́: Bí a ṣe ń fojúsí àti bí aṣe ń f’etí sílẹ̀ láti mọ ìgbà tí àwọn ọmọ bá ń báwa sọ̀rò láti báwa pín ǹkan pọ̀ àti ìgbà tì wọ́n bá ń báwa sọ̀rọ̀ láti bèèrè fún ǹkan; bí a ṣe ńṣe àgbékalẹ̀ àwọn ànfààní fún ìbáraẹnisọ̀rọ̀ nínú àwọn ìṣe ojoojúmọ́; àti bí o ṣe lè sàkíyèsí àti bí o ṣe lè fèsì sí ìbáraẹnisọ̀rọ̀ ọmọọ̀ rẹ.
  • Abala Ke̩sàán: Kíkó̩ àwo̩n O̩gbó̩n Titun àti àwo̩n Ìpele Ìránló̩wó̩:

    Nínú abala yìí wàá kó̩ nípa: ọ̀nà láti pín àwo̩n is̩é̩ nlá nlá, bíi as̩o̩ wíwò̩ àti o̩wó̩ fífò̩, sí ìgbésè̩ kékèèké; ọ̀nà láti yan irúfé̩ ìgbésè̩ kékeré tí o lè kó̩kó̩ kó̩; nípa àwo̩n ìpele ìrànló̩wó̩ tí o le pèsè láti ran o̩mo̩ re̩ ló̩wó̩ láti kó̩ àwo̩n ìgbésè̩ náà; ọ̀nà láti fún o̩mo̩ re̩ ní ìrànló̩wó̩ ní ìpele tí ó mọ níwọ̀n, nínú eré àti nínu is̩é̩ ìgbàdégbà inú ilé̩.
  • Abala Ke̩wàá: Níní Òye Ìhùwàsí O̩mo̩ re̩:

    Nínú abala yìí ìwo̩ yíò kó̩ nípa: bí o ṣe lè ní òye àwo̩n ò̩rò̩ tí àwo̩n o̩mo̩dé ngbìyànjú àti fi ráns̩é̩ sí wa nípa lílo ìwà oníjàngbọ̀n; àwo̩n ò̩nà àti dènà àwo̩n ìwà oníjàngbọ̀n náà.
  • Abala Ko̩kànlá: S̩ís̩e Ìdènà Ìwà oníjàngbọ̀n– Ríran àwo̩n O̩mo̩dé lọ́wọ́ lati tẹ̀síwájú lati máa kópa àti làti wà ní ìfarabalè̩:

    Nínú abala yìí ìwo̩ yíò kó̩ nípa: ọ̀nà làti mú kí àwo̩n o̩mo̩de ó wà ní ìfarabalè̩ (farabalè̩, ṣe jẹ́jẹ́, kí ó sì s̩etán àti ke̩kò̩ó̩); àwo̩n ò̩nà làti ní ìmò̩ àti láti s̩e ìdènà àwo̩n ìwà oníjàngbọ̀n náà.
  • Abala Kejìlá: Mímo̩ àwo̩n Okùnfà fún Ìwà Oníjàngbọ̀n:

    Nínú abala yìí wàá kó̩ nípa: ọ̀nà láti lo àwòrán láti jé̩ kí o̩mo̩ re̩ mo̩ oun tó fé̩ s̩e̩lè̩ àti láti gbaradì láti pààrò̩ is̩é̩; ọ̀nà láti mo̩ okùnfà ìwà oníjàngbọ̀n kí o baà lè mo̩ ò̩nà láti fèsì kí ìwà náà baà lè dínkù.
  • Abala Ke̩tàlá: Kíkó̩ ‘ni ni àwo̩n ìhùwàsí mìíràn dípò Ìwà oníjàngbọ̀n:

    Nínú abala yìí ìwo̩ yíò kó̩ síwájú si nípa níní òye àwo̩n okùnfà ìwa oníjàngbọ̀n àti àwo̩n ò̩nà àti fèsì sí àwo̩n ìwà oníjàngbọ̀n náà kí wó̩n má baà ma s̩e̩lè̩ lóòrèkóòrè.
  • Abala Kẹrìnlá: Ṣíṣe àmúlò ẹ̀kọ́ àti níní àfojúsùn:

    Nínú abala yìí ìwo̩ yíò kó̩ nipa ìtè̩síwájú tí ìwo̩ àti o̩mo̩ re̩ ti ní; ṣís̩ètò àwọn àfojúsùn tuntun fún ìbánisò̩rò̩ o̩mo̩ re̩; àti fífẹ àwọn ìṣe ìgbàdégbà yín lójú nípa fífi àwo̩n ìpele titun kún wọn àti sísọ wọ́n pọ̀ mọ́ ara wọn.
  • Abala kẹẹ̀dógún: Wíwá ojutu sí ìṣòro àti títọ́jú ara ẹni:

    Nínú abala yìí, wàá kọ́: nípa àwọn ohun tó ń fa ìnira àti bí a ti ń tọ́jú ara ẹni; àti ọ̀nà lati wá ojutu sí àwọn ìṣòro tí ó lè jẹyọ.

Enroll me for this course

The course is free. Just register for an account on OpenWHO and take the course!
Enroll me now

Certificate Requirements

  • Gain a Record of Achievement by earning at least 80% of the maximum number of points from all graded assignments.
  • Gain an Open Badge by completing the course.